12 Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣe gbogbo ohun tí mo sọ nípa Élì àti nípa ilé rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.+ 13 Sọ fún un pé màá ṣe ìdájọ́ tó máa wà títí láé fún ilé rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mọ̀ nípa rẹ̀,+ torí àwọn ọmọ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run,+ àmọ́ kò bá wọn wí.+