ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Òwe 6:9-11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Ìgbà wo ni ìwọ ọ̀lẹ máa dùbúlẹ̀ dà?

      Ìgbà wo lo máa dìde lójú oorun rẹ?

      10 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,

      Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,+

      11 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,

      Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+

  • Òwe 15:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ọ̀nà ọ̀lẹ dà bí igbó ẹ̀gún,+

      Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin dà bí ọ̀nà tó tẹ́jú.+

  • Òwe 24:30, 31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ oko ọ̀lẹ,+

      Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹni tí kò ní làákàyè.*

      31 Mo rí i pé igbó ti kún bò ó;

      Èsìsì ti bo ilẹ̀ rẹ̀,

      Ògiri olókùúta rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀.+

  • Òwe 26:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ilẹ̀kùn ń yí lórí ìkọ́* rẹ̀,

      Ọ̀lẹ náà ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.+

      15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,

      Àmọ́, ó rẹ̀ ẹ́ débi pé kò lè gbé e pa dà sẹ́nu.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́