ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 32:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  35 Tèmi ni ẹ̀san àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀,+

      Ní àkókò náà tí ẹsẹ̀ wọn máa yọ̀ tẹ̀rẹ́,+

      Torí ọjọ́ àjálù wọn sún mọ́lé,

      Ohun tó sì ń dúró dè wọ́n máa tètè dé.’

  • Òwe 24:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Má sọ pé: “Bó ṣe ṣe sí mi ni màá ṣe sí i pa dà;

      Màá san ohun tó ṣe pa dà fún un.”*+

  • Mátíù 5:38, 39
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Ojú dípò ojú àti eyín dípò eyín.’+ 39 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ má ṣe ta ko ẹni burúkú, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní etí* ọ̀tún, ẹ yí èkejì sí i.+

  • Róòmù 12:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.+ Ẹ jẹ́ kí ìrònú yín dá lé ohun tó dára lójú gbogbo èèyàn.

  • Róòmù 12:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú;*+ nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san, ni Jèhófà* wí.”+

  • 1 Tẹsalóníkà 5:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni ò fi búburú san búburú fún ẹnì kankan,+ kí ẹ sì máa fìgbà gbogbo wá ohun rere fún ara yín àti fún gbogbo àwọn míì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́