Òwe 20:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Má ṣe sọ pé: “Màá fi búburú san búburú!”+ Ní ìrètí nínú Jèhófà,+ yóò sì gbà ọ́ là.+ Róòmù 12:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.+ Ẹ jẹ́ kí ìrònú yín dá lé ohun tó dára lójú gbogbo èèyàn. Róòmù 12:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú;*+ nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san, ni Jèhófà* wí.”+ 1 Tẹsalóníkà 5:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni ò fi búburú san búburú fún ẹnì kankan,+ kí ẹ sì máa fìgbà gbogbo wá ohun rere fún ara yín àti fún gbogbo àwọn míì.+
19 Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú;*+ nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san, ni Jèhófà* wí.”+
15 Ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni ò fi búburú san búburú fún ẹnì kankan,+ kí ẹ sì máa fìgbà gbogbo wá ohun rere fún ara yín àti fún gbogbo àwọn míì.+