-
Jeremáyà 16:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ẹ ti ṣe ohun tó burú gan-an ju ti àwọn baba ńlá yín lọ,+ gbogbo yín ya alágídí, ẹ sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú yín sọ dípò kí ẹ máa ṣègbọràn sí mi.+ 13 Nítorí náà, màá lé yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin tàbí àwọn baba ńlá yín kò mọ̀,+ ibẹ̀ ni ẹ ó ti sin àwọn ọlọ́run míì tọ̀sántòru,+ torí mi ò ní ṣojú rere sí yín.”’
-