-
2 Kíróníkà 36:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 12 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wòlíì Jeremáyà,+ ẹni tó ń sọ ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. 13 Ó tún ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Nebukadinésárì,+ ẹni tó mú kó fi Ọlọ́run búra, ó ya olórí kunkun* àti ọlọ́kàn líle, ó kọ̀, kò yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
-