ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 2:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà Ọlọ́run fi erùpẹ̀+ ilẹ̀ mọ ọkùnrin, ó mí èémí ìyè+ sí ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì di alààyè.*+

  • Jóòbù 27:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Tí èémí mi bá ṣì wà nínú mi,

      Tí ẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wà nínú ihò imú mi,+

  • Jóòbù 34:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Tó bá fiyè* sí wọn,

      Tó bá kó ẹ̀mí àti èémí wọn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,+

      15 Gbogbo èèyàn* jọ máa ṣègbé,

      Aráyé á sì pa dà sí erùpẹ̀.+

  • Sáàmù 104:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Tí o bá gbé ojú rẹ pa mọ́, ìdààmú á bá wọn.

      Tí o bá mú ẹ̀mí wọn kúrò, wọ́n á kú, wọ́n á sì pa dà sí erùpẹ̀.+

  • Àìsáyà 42:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, sọ nìyí,

      Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti Atóbilọ́lá tó nà án jáde,+

      Ẹni tó tẹ́ ayé àti èso rẹ̀,+

      Ẹni tó fún àwọn èèyàn inú rẹ̀ ní èémí,+

      Tó sì fún àwọn tó ń rìn lórí rẹ̀ ní ẹ̀mí:+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́