ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 3:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+

  • Jóòbù 34:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Tó bá fiyè* sí wọn,

      Tó bá kó ẹ̀mí àti èémí wọn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,+

      15 Gbogbo èèyàn* jọ máa ṣègbé,

      Aráyé á sì pa dà sí erùpẹ̀.+

  • Sáàmù 146:3, 4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí*

      Tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là.+

      4 Ẹ̀mí* rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀;+

      Ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.+

  • Oníwàásù 3:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 nítorí pé ohun* kan wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn, ohun kan sì wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko; ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ Bí ọ̀kan ṣe ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní.+ Torí náà, èèyàn kò lọ́lá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni ohun gbogbo. 20 Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ.+ Inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá,+ inú erùpẹ̀ sì ni gbogbo wọn ń pa dà sí.+

  • Oníwàásù 12:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Nígbà náà, erùpẹ̀ á pa dà sí ilẹ̀,+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀mí* á sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fúnni.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́