15 Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+
16 Èyí pẹ̀lú jẹ́ àdánù ńlá: Bí ẹni náà ṣe wá gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa lọ; èrè wo ló sì wà fún ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lórí asán?+