ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 4:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+

  • 1 Àwọn Ọba 4:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Oúnjẹ Sólómọ́nì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun, 23 màlúù àbọ́sanra mẹ́wàá, ogún (20) màlúù láti ibi ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín mélòó kan, àwọn egbin, àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí ó sanra.

  • 1 Àwọn Ọba 10:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 5 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, ẹnu yà á gan-an.*

  • 1 Àwọn Ọba 10:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Gbogbo ohun èlò tí Ọba Sólómọ́nì fi ń mu nǹkan jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì+ sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí ìkankan tí wọ́n fi fàdákà ṣe, nítorí fàdákà kò já mọ́ nǹkan kan nígbà ayé Sólómọ́nì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́