-
1 Sámúẹ́lì 25:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Nígbà tí Ábígẹ́lì tajú kán rí Dáfídì, ní kíá ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó kúnlẹ̀, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú Dáfídì. 24 Ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, jẹ́ kí ẹ̀bi náà wà lórí mi; jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ bá ọ sọ̀rọ̀, kí o sì fetí sí ọ̀rọ̀ tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ fẹ́ sọ.
-
-
Ẹ́sítà 4:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 ó fún Ẹ́sítà lésì pé: “Má rò pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Júù yòókù kò ní kàn ọ́ torí pé o wà nínú agbo ilé ọba. 14 Tí o bá dákẹ́ ní àkókò yìí, àwọn Júù máa rí ìtura àti ìdáǹdè láti ibòmíì,+ ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé bàbá rẹ yóò ṣègbé. Ta ló sì mọ̀ bóyá torí irú àkókò yìí lo fi dé ipò ayaba tí o wà?”+
-