33 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba,+ wọ́n mú kí òdodo fìdí múlẹ̀, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,+ wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,+ 34 wọ́n dáwọ́ agbára iná dúró,+ wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà,+ a sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìlera,+ wọ́n di akíkanjú lójú ogun,+ wọ́n mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá sá lọ.+