3 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.+
Kò ní gbé ìdájọ́ rẹ̀ ka ohun tó fojú rí,
Kò sì ní gbé ìbáwí rẹ̀ ka ohun tó fetí gbọ́ lásán.+
4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,
Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.
Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+
Ó sì máa fi èémí ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+