-
Sáàmù 22:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Gbogbo ayé á rántí, wọ́n á sì yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà.
Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè á tẹrí ba níwájú rẹ.+
-
-
Àìsáyà 66:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “Màá fi àmì kan sáàárín wọn, màá sì rán lára àwọn tó yè bọ́ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè, sí Táṣíṣì,+ Púlì àti Lúdì,+ àwọn tó ń ta ọfà, sí Túbálì àti Jáfánì,+ títí kan àwọn erékùṣù tó wà lọ́nà jíjìn, tí wọn ò tíì gbọ́ ìròyìn nípa mi, tí wọn ò sì tíì rí ògo mi; wọ́n sì máa kéde ògo mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+
-