3 Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé:
“Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe!+
Ẹ la ọ̀nà tó tọ́ + gba inú aṣálẹ̀ fún Ọlọ́run wa.+
4 Kí ẹ mú kí gbogbo àfonífojì ga sókè,
Kí ẹ sì mú kí gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké wálẹ̀.
Kí ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun di ilẹ̀ tó tẹ́jú,
Kí ilẹ̀ kángunkàngun sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀.+