- 
	                        
            
            Àìsáyà 2:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        3 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa lọ, wọ́n á sì sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà, Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+ Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”+ Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+ Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Àìsáyà 11:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        6 Ìkookò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé fúngbà díẹ̀,+ Àmọ̀tẹ́kùn máa dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, Ọmọ màlúù, kìnnìún* àti ẹran tó sanra á jọ wà pa pọ̀;*+ Ọmọ kékeré á sì máa dà wọ́n. 7 Màlúù àti bíárì á jọ máa jẹun, Àwọn ọmọ wọn á sì jọ dùbúlẹ̀. Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù.+ 8 Ọmọ ẹnu ọmú máa ṣeré lórí ihò ṣèbé, Ọmọ tí wọ́n ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ sì máa fọwọ́ sí ihò ejò olóró. 
 
-