16 “Ìwọ ọmọ èèyàn, mú igi kan, kí o sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé, ‘Ti Júdà àti ti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.’*+ Kí o wá mú igi míì, kí o sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé, ‘Ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.’*+
19 sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú igi Jósẹ́fù, tó wà lọ́wọ́ Éfúrémù àti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, èmi yóò sì fi wọ́n mọ́ igi Júdà; èmi yóò sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo,+ wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.”’
11 A ó sì mú kí àwọn èèyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì ṣọ̀kan,+ wọ́n á yan olórí fún ara wọn, wọ́n á sì jáde kúrò ní ilẹ̀ náà, nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà máa jẹ́ ní Jésírẹ́lì.+