-
2 Kíróníkà 32:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Lẹ́yìn náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan, ó sì pa gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú + àti àwọn aṣáájú pẹ̀lú àwọn olórí nínú ibùdó ọba Ásíríà, tó fi di pé ìtìjú ló fi pa dà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀. Nígbà tó yá, ó wọ ilé* ọlọ́run rẹ̀, ibẹ̀ ni àwọn kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ti fi idà pa á.+ 22 Bí Jèhófà ṣe gba Hẹsikáyà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ Senakérúbù ọba Ásíríà nìyẹn àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn yòókù, ó sì fún wọn ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká.
-
-
Àìsáyà 31:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ó máa sá lọ nítorí idà,
Wọ́n sì máa fipá kó àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́.
-