-
Jeremáyà 47:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
47 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nìyí fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn Filísínì,+ kí Fáráò tó pa Gásà run.
-
-
Jóẹ́lì 3:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,
Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?
Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?
Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,
Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+
-
-
Sefanáyà 2:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nítorí Gásà máa di ìlú tí a pa tì;
Áṣíkẹ́lónì á sì di ahoro.+
-
-
Sekaráyà 9:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Áṣíkẹ́lónì á rí i, ẹ̀rù á sì bà á;
Gásà yóò jẹ̀rora,
Bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ́kírónì, torí pé ìrètí rẹ̀ ti di ìtìjú.
Ọba kan yóò ṣègbé ní Gásà,
Ẹnì kankan kò sì ní gbé ní Áṣíkẹ́lónì.+
-