5 “Ẹ wo àwọn orílẹ̀-èdè kí ẹ sì kíyè sí i!
Kí ẹnu yà yín bí ẹ ṣe ń wò wọ́n, kí ó sì jọ yín lójú;
Torí ohun kan máa ṣẹlẹ̀ lásìkò yín,
Tí ẹ ò ní gbà gbọ́ tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ ọ́ fún yín.+
6 Mò ń gbé àwọn ará Kálídíà dìde,+
Orílẹ̀-èdè tí kò lójú àánú, tí kì í fi nǹkan falẹ̀.
Wọ́n yára bolẹ̀ káàkiri ayé
Láti gba àwọn ilé tí kì í ṣe tiwọn.+
7 Wọ́n ń dẹ́rù bani, wọ́n sì ń kóni láyà jẹ.
Wọ́n ń gbé ìdájọ́ àti àṣẹ tiwọn kalẹ̀.+