40 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì má bàa ṣẹ sí yín lára, pé: 41 ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣègbé, nítorí mò ń ṣe iṣẹ́ kan lásìkò yín, iṣẹ́ tí ẹ ò ní gbà gbọ́ láé bí ẹnì kan bá tiẹ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ fún yín.’”+