-
Diutarónómì 16:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ.
-
-
Jeremáyà 33:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ní ibí yìí tí ẹ̀ ń sọ pé ó jẹ́ aṣálẹ̀, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn níbẹ̀, ní àwọn ìlú Júdà àti àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù tó ti di ahoro, tí kò sí èèyàn tàbí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ àti ẹran ọ̀sìn, ibẹ̀ ni a ó tún ti pa dà gbọ́ 11 ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú,+ ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó, ohùn àwọn tó ń sọ pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé!”’+
“‘Wọ́n á mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà,+ nítorí màá mú àwọn tí wọ́n kó lọ sí oko ẹrú láti ilẹ̀ náà pa dà wá bíi ti ìbẹ̀rẹ̀,’ ni Jèhófà wí.”
-