ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 60:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 A ò ní gbúròó ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ,

      A ò sì ní gbúròó ìparun àti ìwópalẹ̀ nínú àwọn ààlà rẹ.+

      O máa pe àwọn ògiri rẹ ní Ìgbàlà,+ o sì máa pe àwọn ẹnubodè rẹ ní Ìyìn.

  • Àìsáyà 65:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé,

      Wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.

      Torí pé ọjọ́ àwọn èèyàn mi máa dà bí ọjọ́ igi,+

      Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

  • Jeremáyà 23:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Júdà máa rí ìgbàlà ní ìgbà ayé rẹ̀,+ Ísírẹ́lì sì máa wà ní ààbò.+ Orúkọ tí a ó sì máa pè é ni, Jèhófà Ni Òdodo Wa.”+

  • Ìsíkíẹ́lì 34:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà,+ èmi yóò sì pa àwọn ẹranko ẹhànnà run ní ilẹ̀ náà,+ kí wọ́n lè máa gbé láìséwu nínú aginjù, kí wọ́n sì sùn nínú igbó.+

  • Hósíà 2:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní ọjọ́ yẹn, màá bá àwọn ẹran inú igbó dá májẹ̀mú nítorí wọn,+

      Màá sì bá àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ohun tó ń rákò lórí ilẹ̀ dá májẹ̀mú;+

      Màá mú ọfà* àti idà àti ogun kúrò ní ilẹ̀ náà,+

      Màá sì jẹ́ kí wọ́n dùbúlẹ̀* ní ààbò.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́