14 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì sọ fún mi pé: “Kéde pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo ní ìtara tó pọ̀ fún Jerúsálẹ́mù àti fún Síónì.+ 15 Inú bí mi gan-an sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ara tù,+ torí mi ò bínú púpọ̀ sí àwọn èèyàn mi,+ àmọ́ wọ́n dá kún àjálù náà.”’+