Àìsáyà 49:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì máa yọ̀, ìwọ ayé.+ Kí inú àwọn òkè dùn, kí wọ́n sì kígbe ayọ̀.+ Torí Jèhófà ti tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú,+Ó sì ń ṣàánú àwọn èèyàn rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.+ Àìsáyà 51:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+ Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+ Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+ 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Ìyìn ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi,+ Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,+ 4 ẹni tó ń tù wá nínú* nínú gbogbo àdánwò* wa,+ kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀+ tu àwọn míì nínú+ lábẹ́ àdánwò* èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.
13 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì máa yọ̀, ìwọ ayé.+ Kí inú àwọn òkè dùn, kí wọ́n sì kígbe ayọ̀.+ Torí Jèhófà ti tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú,+Ó sì ń ṣàánú àwọn èèyàn rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.+
3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+ Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+ Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+
3 Ìyìn ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi,+ Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,+ 4 ẹni tó ń tù wá nínú* nínú gbogbo àdánwò* wa,+ kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀+ tu àwọn míì nínú+ lábẹ́ àdánwò* èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.