25 Lẹ́yìn rẹ̀, Pálálì ọmọ Úṣáì ṣe iṣẹ́ àtúnṣe níwájú Ìtì Ògiri àti ilé gogoro tó yọ jáde láti Ilé Ọba,*+ ti apá òkè tó jẹ́ ti Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Lẹ́yìn rẹ̀, ó kan Pedáyà ọmọ Páróṣì.+
21 Nítorí náà, Ọba Sedekáyà ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì ń fún un ní ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójúmọ́ láti òpópónà àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì,+ títí gbogbo búrẹ́dì ìlú náà fi tán.+ Jeremáyà kò sì kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.