4 Jèhófà á sì mú ìlérí tó ṣe nípa mi ṣẹ, pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá fiyè sí ọ̀nà wọn, láti fi òtítọ́ rìn níwájú mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara* wọn,+ kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ* tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+
32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+