13 Ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘àní bí mo tiẹ̀ bá yín sọ̀rọ̀ léraléra,* ẹ kò fetí sílẹ̀.+ Mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn.+14 Bí mo ti ṣe sí Ṣílò, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé+ àti sí ibi tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.+