-
Jeremáyà 44:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Màá sì kó àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n ti pinnu láti lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì kí wọ́n lè máa gbé ibẹ̀, gbogbo wọn sì máa ṣègbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Idà yóò pa wọ́n, ìyàn yóò sì mú kí wọ́n ṣègbé; látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, idà àti ìyàn ni yóò pa wọ́n. Wọ́n á sì di ẹni ègún, ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn.+ 13 Ṣe ni màá fìyà jẹ àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, bí mo ṣe fìyà jẹ Jerúsálẹ́mù nípasẹ̀ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn.*+ 14 Àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n lọ ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì kò ní lè sá àsálà tàbí kí wọ́n yè bọ́ láti pa dà sí ilẹ̀ Júdà. Á wù wọ́n* pé kí wọ́n pa dà, kí wọ́n sì máa gbé ibẹ̀, àmọ́ wọn ò ní lè pa dà, àyàfi àwọn díẹ̀ tó máa sá àsálà.’”
-
-
Jeremáyà 44:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Wò ó, ojú mi wà lára wọn fún àjálù, kì í ṣe fún ohun rere;+ gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì ni idà àti ìyàn yóò pa, títí wọn kò fi ní sí mọ́.+ 28 Àwọn díẹ̀ ló máa bọ́ lọ́wọ́ idà, tí wọ́n á sì pa dà láti ilẹ̀ Íjíbítì sí ilẹ̀ Júdà.+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nílẹ̀ Júdà, tí wọ́n wá sí ilẹ̀ Íjíbítì láti máa gbé ibẹ̀, máa mọ ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, bóyá tèmi ni tàbí tiwọn!”’”
-