- 
	                        
            
            Àìsáyà 15:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        Ìdí nìyẹn tí àwọn ọkùnrin Móábù tó dira ogun fi ń kígbe ṣáá. Ó* ń gbọ̀n rìrì. 5 Ọkàn mi ń ké jáde torí Móábù. Àwọn tó sá níbẹ̀ ti sá lọ sí Sóárì+ àti Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà+ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Lúhítì; Wọ́n ń ké lójú ọ̀nà Hórónáímù torí àjálù náà.+ 6 Torí omi Nímúrímù ti gbẹ táútáú; Koríko tútù ti gbẹ dà nù, Kò sí koríko mọ́, kò sì sí ewéko tútù kankan mọ́. 
 
-