2 Ó ti gòkè lọ sí Ilé àti sí Díbónì,+
Lọ sí àwọn ibi gíga láti sunkún.
Móábù ń sunkún torí Nébò+ àti torí Médébà.+
Wọ́n fá gbogbo orí korodo,+ wọ́n gé gbogbo irùngbọ̀n mọ́lẹ̀.+
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ lójú ọ̀nà.
Gbogbo wọn ń pohùn réré ẹkún lórí àwọn òrùlé àtàwọn ojúde ìlú wọn;
Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ.+