ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 79:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Wọ́n ti fi òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run,

      Wọ́n sì ti fi ẹran ara àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ fún àwọn ẹran inú igbó.+

       3 Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi káàkiri Jerúsálẹ́mù,

      Kò sì sí ẹni tó ṣẹ́ kù tó máa sin wọ́n.+

  • Àìsáyà 5:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ̀,

      Ó sì máa na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí wọn, ó máa lù wọ́n.+

      Àwọn òkè máa mì tìtì,

      Òkú wọn sì máa dà bí ààtàn lójú ọ̀nà.+

      Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

      Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.

  • Jeremáyà 7:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 Òkú àwọn èèyàn yìí á di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+

  • Jeremáyà 9:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

      “Òkú àwọn èèyàn á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀

      Àti bí ìtí ọkà tí olùkórè ṣẹ̀ṣẹ̀ gé sílẹ̀,

      Tí ẹnì kankan kò ní kó jọ.”’”+

  • Jeremáyà 36:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí sí Jèhóákímù ọba Júdà, ‘Kò ní lẹ́nì kankan tó máa jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì,+ òkú rẹ̀ á sì wà ní ìta nínú ooru lọ́sàn-án àti nínú òtútù lóru.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́