ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 21:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Mánásè ta ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ débi pé ó kún Jerúsálẹ́mù láti ìkángun kan dé ìkángun kejì,+ yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ èyí tí ó mú Júdà ṣẹ̀, tí wọ́n fi ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.

  • Àìsáyà 59:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Ẹsẹ̀ wọn ń sáré láti hùwà burúkú,

      Wọ́n sì ń yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+

      Ohun burúkú ni wọ́n ń rò;

      Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn.+

  • Jeremáyà 2:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Kódà, ẹ̀jẹ̀ àwọn* aláìní tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ti ta sí ọ láṣọ,+

      Kì í ṣe torí pé wọ́n ń fọ́lé ni o fi pa wọ́n;

      Síbẹ̀, mo ṣì rí ẹ̀jẹ̀ wọn lára gbogbo aṣọ rẹ.+

  • Ìdárò 4:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ àti àṣìṣe àwọn àlùfáà rẹ̀,+

      Tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàárín rẹ̀.+

  • Mátíù 23:34, 35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Torí èyí, mò ń rán àwọn wòlíì,+ àwọn amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba+ sí yín. Ẹ máa pa àwọn kan lára wọn,+ ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi,* ẹ máa na àwọn kan lára wọn+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn+ láti ìlú dé ìlú, 35 kí ẹ lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn olódodo tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ayé, látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ olódodo dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà ọmọ Barakáyà, ẹni tí ẹ pa láàárín ibi mímọ́ àti pẹpẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́