-
Diutarónómì 28:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá+ rẹ ṣẹ́gun rẹ. Ọ̀nà kan lo máa gbà yọ sí wọn láti bá wọn jà, àmọ́ ọ̀nà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo máa gbà sá kúrò lọ́dọ̀ wọn; o sì máa di ohun àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba+ ayé. 26 Òkú rẹ á di oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àtàwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+
-
-
Sáàmù 79:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Wọ́n ti fi òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run,
Wọ́n sì ti fi ẹran ara àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ fún àwọn ẹran inú igbó.+
-
-
Jeremáyà 7:33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Òkú àwọn èèyàn yìí á di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+
-