11 Hírámù tún ṣe àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́.+
Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí iṣẹ́ tó ṣe fún Ọba Sólómọ́nì ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn:+ 12 àwọn òpó méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; iṣẹ́ ọnà méjèèjì+ tó dà bí àwọ̀n tó fi bo ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó náà;