14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+
8 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn wòlíì yín àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín tó wà láàárín yín tàn yín jẹ,+ ẹ má sì fetí sí àlá tí wọ́n ń lá.