12 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé, ìyẹn àwọn àgbààgbà tó mọ bí ilé náà ṣe rí tẹ́lẹ̀,+ sunkún kíkankíkan nígbà tí wọ́n rí i tí à ń fi ìpìlẹ̀ ilé yìí lélẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì ń kígbe ayọ̀ bí ohùn wọn ṣe ròkè tó.+
17 Bí gbogbo àwùjọ* àwọn tó dé láti ìgbèkùn ṣe ṣe àwọn àtíbàbà nìyẹn, wọ́n sì ń gbé inú àwọn àtíbàbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe é báyìí rí láti ìgbà ayé Jóṣúà+ ọmọ Núnì títí di ọjọ́ yẹn, ìdí nìyẹn tí ìdùnnú fi ṣubú layọ̀ láàárín wọn.+