-
Jeremáyà 33:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: ‘Ní aṣálẹ̀ yìí, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn nínú rẹ̀ àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ibi ìjẹko yóò tún pa dà wà fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí agbo ẹran wọn máa dùbúlẹ̀ sí.’+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 36:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Màá mú kí àwọn èèyàn rẹ pọ̀ sí i, gbogbo ilé Ísírẹ́lì, gbogbo rẹ̀ pátá, wọ́n á máa gbé inú àwọn ìlú náà,+ wọ́n á sì tún àwọn àwókù náà kọ́.+ 11 Àní màá sọ àwọn èèyàn rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ di púpọ̀;+ wọ́n á bí sí i, wọ́n á sì pọ̀ sí i. Èmi yóò mú kí wọ́n máa gbé inú rẹ bíi ti tẹ́lẹ̀,+ èmi yóò sì mú kí nǹkan dáa fún yín ju ti tẹ́lẹ̀ lọ;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
-