ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 51:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+

      Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+

      Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+

      Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+

      Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,

      Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+

  • Jeremáyà 30:18, 19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

      “Wò ó, màá kó àwọn tó lọ sí oko ẹrú láti àgọ́ Jékọ́bù jọ,+

      Máa sì ṣojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀.

      Wọ́n á tún ìlú náà kọ́ sórí òkìtì rẹ̀,+

      Ibi tó sì yẹ ni wọ́n á kọ́ ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò sí.

      19 Ìdúpẹ́ àti ohùn ẹ̀rín á ti ọ̀dọ̀ wọn wá.+

      Màá sọ wọ́n di púpọ̀, wọn ò sì ní kéré níye;+

      Màá mú kí wọ́n pọ̀ níye,*

      Wọn ò sì ní jẹ́ ẹni yẹpẹrẹ.+

  • Émọ́sì 9:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Màá kó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn pa dà,+

      Wọ́n á tún àwọn ìlú tó ti di ahoro kọ́, wọ́n á sì máa gbé inú wọn;+

      Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n á sì mu wáìnì wọn,+

      Wọ́n á ṣe ọgbà, wọ́n á sì jẹ èso wọn.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́