12 “Síbẹ̀, ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi báyìí,” ni Jèhófà wí,+
“Kí ẹ gbààwẹ̀,+ kí ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún.
13 Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+
Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,
Torí ó ń gba tẹni rò, ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+
Òun yóò sì pèrò dà nípa àjálù náà.
14 Ta ló mọ̀ bóyá ó máa tún ìpinnu ṣe, kó sì pèrò dà,+
Kó sì mú kí ìbùkún ṣẹ́ kù fún yín,
Kí ẹ lè fi ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà Ọlọ́run yín?