ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 30:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+

      Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*

      Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!

  • Jeremáyà 44:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Màá sì kó àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n ti pinnu láti lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì kí wọ́n lè máa gbé ibẹ̀, gbogbo wọn sì máa ṣègbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Idà yóò pa wọ́n, ìyàn yóò sì mú kí wọ́n ṣègbé; látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, idà àti ìyàn ni yóò pa wọ́n. Wọ́n á sì di ẹni ègún, ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn.+

  • Ìsíkíẹ́lì 17:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹgbẹ́ ogun Fáráò àti àwọn ọmọ ogun wọn kò ní lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ogun,+ nígbà tí wọ́n bá mọ òkìtì láti dó tì í, tí wọ́n sì mọ odi kí wọ́n lè gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn.* 18 Ó ti fojú kéré ìbúra, ó sì ti da májẹ̀mú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣèlérí,* ó ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, kò sì ní yè bọ́.”’

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́