5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+
31 Ọlọ́run gbé ẹni yìí ga sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ láti jẹ́ Olórí Aṣojú+ àti Olùgbàlà,+ kí ó lè mú kí Ísírẹ́lì ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+