-
Ìsíkíẹ́lì 25:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+ 13 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 36:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn yìí ni pé: ‘Èmi yóò fi ìtara mi tó ń jó bí iná+ sọ̀rọ̀ sí àwọn tó là á já nínú àwọn orílẹ̀-èdè àti sí gbogbo Édómù, àwọn tí inú wọn dùn gan-an, tí wọ́n sì fi mí ṣẹlẹ́yà*+ nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ mi di ohun ìní wọn, kí wọ́n lè gba àwọn ibi ìjẹko inú ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì kó ohun tó wà nínú rẹ̀.’”’+
-