4 Èmi yóò yí ojú rẹ pa dà, màá fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu,+ èmi yóò sì mú ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ jáde,+ àwọn ẹṣin àti àwọn tó ń gẹṣin tí gbogbo wọn wọṣọ iyì, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn pẹ̀lú àwọn apata ńlá àti asà,* gbogbo wọn ní idà;
15 O máa wá láti àyè rẹ, láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá,+ ìwọ àti ọ̀pọ̀ èèyàn pẹ̀lú rẹ, tí gbogbo wọn gun ẹṣin, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn, àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an.+