11 Màá gbé àgọ́ ìjọsìn mi sáàárín yín,+ mi* ò sì ní kọ̀ yín. 12 Èmi yóò máa rìn láàárín yín, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì jẹ́ èèyàn mi.+
26 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà;+ májẹ̀mú ayérayé ni màá bá wọn dá. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, màá sọ wọ́n di púpọ̀,+ màá sì fi ibi mímọ́ mi sí àárín wọn títí láé. 27 Àgọ́* mi yóò wà pẹ̀lú* wọn, èmi yóò di Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.+