19 Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan,*+ màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn;+ màá mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn,+ màá sì fún wọn ní ọkàn ẹran,*+20 kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, kí wọ́n sì máa rìn nínú rẹ̀. Wọ́n á wá di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.”’
“Ọmọ èèyàn, ibi ìtẹ́ mi+ àti ibi tí màá gbé ẹsẹ̀ mi sí nìyí,+ ibẹ̀ ni èmi yóò máa gbé títí láé láàárín àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.+ Ilé Ísírẹ́lì àti àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àti òkú àwọn ọba wọn nígbà tí wọ́n bá kú sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin mọ́.+
3 Ni mo bá gbọ́ ohùn kan tó dún ketekete látorí ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn.+