11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+
12 Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà àti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn àti sí ọ̀rọ̀ wòlíì Hágáì, torí Jèhófà Ọlọ́run wọn ló rán an; àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà.