ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 25:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Bí Ísírẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jọ́sìn* Báálì Péórì+ nìyẹn, inú sì bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì.

  • Àwọn Onídàájọ́ 2:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, wọ́n sì sin* àwọn Báálì.+

  • Àwọn Onídàájọ́ 2:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì sin Báálì àti àwọn ère Áṣítórétì.+

  • 2 Kíróníkà 28:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó fi irin ṣe ère*+ àwọn Báálì.

  • Jeremáyà 11:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ẹni tó gbìn ọ́,+ ti kéde pé àjálù yóò bá ọ nítorí ìwà ibi tí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà hù, tí wọ́n ń mú mi bínú bí wọ́n ṣe ń rú ẹbọ sí Báálì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́