-
Máàkù 12:35-37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Bí Jésù ṣe ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó sọ pé: “Kí nìdí tí àwọn akọ̀wé òfin fi sọ pé ọmọ Dáfídì ni Kristi?+ 36 Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́,+ Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.”’+ 37 Dáfídì fúnra rẹ̀ pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe wá jẹ́ ọmọ rẹ̀?”+
Èrò rẹpẹtẹ náà ń gbádùn ọ̀rọ̀ rẹ̀.
-