-
Ẹ́kísódù 26:31-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 “Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe aṣọ ìdábùú.+ Kí o kó iṣẹ́ sí i lára, kí iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù. 32 Kí o gbé e kọ́ sára òpó igi bọn-ọ̀n-ní mẹ́rin tí wọ́n fi wúrà bò. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn. Kí àwọn òpó náà wà lórí ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò tí wọ́n fi fàdákà ṣe. 33 Kí o fi aṣọ ìdábùú náà kọ́ sábẹ́ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí Ẹ̀rí náà+ wọnú ibi tí aṣọ ìdábùú náà bò. Aṣọ ìdábùú náà ni kí ẹ fi pín Ibi Mímọ́+ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+
-